Imú Eerin

Elephant nose

Elephant's nose


By African Storybook

Illustrated by Wiehan de Jager

Translated by
Segun Soetan
Victor Williamson
African StorybookFrom source www.africanstorybook.org

Available under Creative Commons: Attribution 3.0

In Language

Gbogbo ènìyàn mọ̀ pé eerin ní imú gígùn.
Everybody know elephants be having long noses.
Everyone knows that elephants have long noses.
EbonicsYorùbáEnglish
1
Ṣùgbọ́n ní àyé àtijọ́, imú eerìn kúrú ó sì tóbi.
Some time ago though, elephant nose was all short and stubby looking.
But a long time ago, the elephant's nose was short and fat.
EbonicsYorùbáEnglish
2
Lẹ́yìn tí wọ́n bí ọmọ eerin kan. Ó bẹ púpọ̀. Kò sí ẹranko tí kò ní ìbéèrè fún.
Then one day Baby Elephant was born. She was so inquisitive, with questions for all the other animals.
A baby elephant was born. She was very curious.She had a question for every animal.
EbonicsYorùbáEnglish
3
Ó fẹ́ mọ́ nípa àgùnfọn. Ó bèrè lọ́wọ́ àgùnfọn “Kí ló dé tí o ní ọrùn gígùn?"
With curiosity she say to Giraffe, "Why you be having a long neck?"
She was curious about Giraffe."Why do you have a long neck?" she asked.
EbonicsYorùbáEnglish
4
Bákan náà ní ó bèrè lọ́wọ́ Túrùkí. "Kí lo dé tí ó ni ìhò tí ó ní orí ṣóńṣó?"
Then she was asking Rhino, "Why your horn piercing and sharp?"
She was curious about Rhino. "Why does your horn have a sharp point?" she asked.
EbonicsYorùbáEnglish
5
Ó tún fẹ́ mọ̀ nípa Ọ̀ọ̀nì náà. Ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Kí ni àwọn ọ̀ọ̀nì máa ń jẹ fún oúnjẹ alẹ́?”
About Crocodile she asked, "What crocodiles be eating for dinner?"
She was very curious about Crocodile."What do crocodiles eat for dinner?" she asked.
EbonicsYorùbáEnglish
6
Ẹyẹ Àgbìgbò ọlọ́gbọ́n kan dáa lóhùn, “Tẹ̀lé mi lọ sí odò, níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti rí ohun tí ọ̀ọ̀nì ń jẹ fún oúnjẹ alẹ́.”
Clever Crow caught on to Baby Elelphant's curiosity and told her, "Come with me to the river so I can show you what crocodiles like to eat for dinner."
Clever Crow quickly said, "Follow me to the river. There you will see what crocodiles eat for dinner."
EbonicsYorùbáEnglish
7
Ọmọ Eerin tẹ̀lé àgbìgbò lọ sí odò.
So, Baby Elephant went with Crow to the river.
So Baby Elephant followed Crow to the river.
EbonicsYorùbáEnglish
8
Ó rìn kọjá láàárín àwọn koríkò etí odò láti lè dúró létí odò. Ó wo inú odò. “Níbo ni Ọ̀ọ̀ni wà?”
She pushed all the reeds out her way and stood there on the river's edge, peering deeply into the river. Where Crocodile at?
She pushed through the reeds and stood on the bank. She looked into the water.Where was Crocodile?
EbonicsYorùbáEnglish
9
Òkùta kan tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò náà kí i pé “báwo ni?” Ọmọ Eerin náà dáhùn pé “dáádá ni.” O ní “ ṣe o lè sọ fún mi ohun tí Ọ̀ọ̀nì mán ń jẹ fún oúnjẹ alẹ́?”
"What up sis?" say some scaly looking thing on the surface of the water. "I'm good, you?" replied Baby Elephant, "Can you tell me what do crocodiles be eating for dinner?"
"Hello," said a stone near the river bank."Hello," said Baby Elephant."Can you tell me what crocodiles eat for dinner?" she asked.
EbonicsYorùbáEnglish
10
Òkùta náà dáhùn pé “ súnmọ́ ibí yìí, n óò sọ ọ́ fún ẹ.” Ọmọ Eerin dorí kodò.

Okùta ní “Súnmọ́ ibí dáadáa.” Ọmọ Eerin túbọ̀ dorí kodò.
The thing in the water was like, "Come a little closer sweetheart so I can tell you." Baby Elephant leaned over and heard something again, "Come a little closer baby." Baby Elephant put his nose out over the water.
"Come closer and I will tell you," said the stone. Baby Elephant bent down.

"Come closer," said the stone.Baby Elephant bent down lower.
EbonicsYorùbáEnglish
11
Lójijì ! À fi pàkà!

Ọ̀ọ̀ni di eyín mọ́ imú ọmọ Eerin.
Then just like that, Snap!

Crocodile clamped his sharp teeth down on Baby Elephant's nose.
Suddenly! Snap!

Crocodile grabbed Baby Elephant's nose in his jaws.
EbonicsYorùbáEnglish
12
Ọmọ Eerin jókòó, ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ di ilẹ̀ mú, ó ń fá imú rẹ̀ kúrò lẹ́nu Ọ̀ọ̀nì.

Ṣùgbọ́n Ọ̀ọ̀nì kò ju imú rẹ̀ sílẹ̀
Baby Elephant shrieked and pulled back on her hind legs doing everything she could to get free. She pulled and pulled, but Crocodile didn't be letting go for shit.
Baby Elephant sat back on her strong legs and pulled.And pulled, and pulled.

But Crocodile did not let go of her nose.
EbonicsYorùbáEnglish
13
Bí ọmọ Eerin ṣe ń fa imú rẹ̀ kúrò lẹnu Ọ̀ọ̀ni, ní imú rẹ̀ ń gùn sí, imú rẹ̀ ń gùn lọ.

Kò pẹ́, ọmọ Eerin ṣubú. “kòròbàtà!!”
Baby Elephant nose started getting longer and longer, and stretched out till it slipped out Crocodile's mouth and she fell back. "Plop!!"
Baby Elephant's nose stretched and stretched.And stretched.

Until she fell over."Dufff!!"
EbonicsYorùbáEnglish
14
Imú ọmọ Eerin tí ó kúrú tẹ́lẹ̀ tí gùn jádé.
Baby Elephant nose used to be short, but now it was a long trunk.
Baby Elephant's short nose had stretched into a long nose.
EbonicsYorùbáEnglish
15
Imú rẹ̀ gùn gan-an ni, kódà ó lè fi imú rẹ̀ já èèso láti ara ẹ̀ka-igi tí ó ga fíofío.

Títí di òní, Eerin ní imú ti ó gùn tí ó sì wúlò fún un.
Her trunk was even long enough to reach fruit from the branches of tall trees.

All the way till today, elephants trunks long and strong.
Her nose was so long she could pick fruit from high branches.

And to this day, all elephants have long and useful trunks.
EbonicsYorùbáEnglish
16
The end.
Elephant nose